9 “Kí ni ẹ rò pé baba olóko yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣélẹ́. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀.
10 Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹṣẹ yìí nínú ìwé mímọ́:“ ‘Òkúta tí àwọn ọmọ̀lé ti kọ̀ sílẹ̀òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwaó sì jẹ́ ìyàlénu lójú tiwa’?”
12 Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olúkọ̀ òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà fẹ́ mú Jésù lákókò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.
13 Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Hẹ́rọ́dù wá sọ́dọ̀ Jésù, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú.
14 Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ tìrẹ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Késárì?
15 Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”