14 “Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró ní bí tí kò tọ́, tí a tí ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Jùdíà sá lọ sí orí òkè.
15 Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọkalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má si ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.
16 Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà ṣẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀.
17 ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún fọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí.
18 Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé kí ìsákúrò nínú ewu yìí má ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù.
19 Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
20 À fi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.