21 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kírísítì nìyìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.
22 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tàn àwọn ọmọ Ọlọ́run pàápàá jẹ.
23 Nítorí náà, ẹ sọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!
24 “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,“ ‘òòrùn yóò sókùnkùn,òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
25 Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run.Ṣánmọ̀ àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ yóò wárìrì.’
26 “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ-Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọ̀sánmọ̀pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.
27 Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ láti kó àwọn àyànfẹ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aye láti ìkángun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.