28 “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kan lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ titun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fi hàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé.
29 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àwọn ohun abàmì wọ̀n-ọn-nì tí mo ti sọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tan, lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.
30 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Iran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ
31 Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.
32 “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n. Ọlọ́run Baba nìkan ló mọ̀ ọ́n.
33 Ẹ máa sọra, Ẹ má ṣe sùn kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà ní ó àkókò ná yóò dé.
34 Ohun tí a lè fi bíbọ̀ mi wé ni ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò sí orílẹ̀ èdè mìíràn. Kí ó tó lọ, ó pín iṣẹ́ fún àwọn tí ó gbà ṣíṣẹ́, àní, iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe nígbà tí ó bá lọ, ó ní kí ọ̀kan nínú wọn dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà títí òun yóò fi dé.