29 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àwọn ohun abàmì wọ̀n-ọn-nì tí mo ti sọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tan, lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.
30 Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Iran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ
31 Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.
32 “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n. Ọlọ́run Baba nìkan ló mọ̀ ọ́n.
33 Ẹ máa sọra, Ẹ má ṣe sùn kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà ní ó àkókò ná yóò dé.
34 Ohun tí a lè fi bíbọ̀ mi wé ni ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò sí orílẹ̀ èdè mìíràn. Kí ó tó lọ, ó pín iṣẹ́ fún àwọn tí ó gbà ṣíṣẹ́, àní, iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe nígbà tí ó bá lọ, ó ní kí ọ̀kan nínú wọn dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà títí òun yóò fi dé.
35 “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí sọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò da. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.