34 Ohun tí a lè fi bíbọ̀ mi wé ni ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò sí orílẹ̀ èdè mìíràn. Kí ó tó lọ, ó pín iṣẹ́ fún àwọn tí ó gbà ṣíṣẹ́, àní, iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe nígbà tí ó bá lọ, ó ní kí ọ̀kan nínú wọn dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà títí òun yóò fi dé.
35 “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí sọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò da. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.
36 Pé nígbà tí bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun.
37 Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí ì fuń gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”