1 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni Àjọ ìrékọjá àti àjọ tí wọ́n ń fi àkàrà àìwú se ku ọ̀túnla. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jésù ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á.
2 Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ Àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”
3 Nígbà tí ó sì wà ní Bẹ́tanì ni ilé Símónì adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti ìgò òróró ìpara olówó iyebíye, ó sí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jésù lórí.
4 Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò?
5 Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.
6 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé? Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi?
7 Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.