18 Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jésù wí pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fí mí hàn.”
19 Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọkọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”
20 Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi jẹun nísinsin yìí ni.
21 Ní tòótọ́ Ọmọ-Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ-Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
22 Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jésù mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”
23 Ó sì tún gbé ago wáìnì, ó gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.
24 Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú túntún, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.