25 Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run.”
26 Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè ólífì lọ.
27 Jésù sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ń bọ̀ wá kosẹ̀ lára mi ni oru òní, a ti kọ̀wé rẹ pé:“ ‘Èmi yóò lu olùsọ́-àgùntànàwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’
28 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò ṣíwájú yin lọ sí Gálílì.”
29 Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”
30 Jésù wá wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tóó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ̀ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”
31 Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.