4 Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò?
5 Òun ìbá tà á ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn talákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.
6 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé? Nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi?
7 Nígbà gbogbo ni àwọn talákà wà ní àárin yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.
8 Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, Ó ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúra sílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi.
9 Lóótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”
10 Nígbà náà ni Júdásì Ìsíkáríọtù, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá, láti ṣètò bí yóò ti fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.