49 Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹ́ḿpìlì, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.”
50 Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sá lọ.
51 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà.
52 Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.
53 Wọ́n mú Jésù lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù àti àwọn olùkọ́-òfin wọn péjọ síbẹ̀.
54 Pétérù tẹ̀lé Jésù lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.
55 Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí.