55 Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí.
56 Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ̀n ní kò bá ara wọn mu
57 Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní
58 “A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹ́ḿpìlì tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ”
59 Ṣíbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba
60 Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ?”
61 Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́.Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ò ní, “Ṣé ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run?”