11 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Bárábà dá sílẹ̀ fún wọn.
12 Pílátù sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”
13 Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”
14 Nígbà náà ni Pílátù bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
15 Pilatù sì ń fẹ́ se èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jésù tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
16 Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú gbangba (tí a ń pè ní Piretorioni), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun jọ.
17 Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.