13 Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”
14 Nígbà náà ni Pílátù bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
15 Pilatù sì ń fẹ́ se èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jésù tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
16 Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú gbangba (tí a ń pè ní Piretorioni), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun jọ.
17 Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí.
18 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù
19 Wọ́n sì fi ọ̀pá ìyè lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ síi lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.