18 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, Ọba àwọn Júù
19 Wọ́n sì fi ọ̀pá ìyè lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ síi lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.
20 Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.
21 Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Símónì ni orúkọ rẹ̀. Ará Kírénì ni. Òun ni baba Alekisáńdérù àti Rúfọ́ọ̀sì. Wọ́n sì mú un nípá, pé kí ó rú àgbélébùú Jésù.
22 Wọ́n sì mú Jésù wá sí Gọ́lgọ́tà, (èyí tí ìtúmọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí)
23 Wọ́n sì fi wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.
24 Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn báà lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.