2 Pílátù sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”Jésù sì dáhùn pé, “Ìwọ wí.”
3 Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án.
4 Pílátù sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.”
5 Ṣùgbọ́n Jésù kò da lohùn síbẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pílátù.
6 Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àsà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún àwọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún.
7 Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bárábà. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n sọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn.
8 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pílátù, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.