31 Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í sẹ̀sín láàrin ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà.
32 Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
33 Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án.
34 Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ?” ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
35 Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”
36 Nígbà náà ni ẹnìkan wá sáré lọ ki kàn-ìn-kàn-ìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jésù kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Èlíjà yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀.”
37 Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.