38 Aṣọ ìkélé tẹ́ḿpìlì sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.
39 Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jésù rí i tí kígbe sókè báyìí tí ó sì èémí ìgbẹ̀yìn, ó wí pé, “Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í se.”
40 Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè. Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè.
41 Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Gálílì máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìranṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerúsálémù.
42 Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí se, ọjọ́ tó sáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú,
43 Jóṣẹ́fù ará Arimatíyà wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pílátù láti tọrọ òkú Jésù.
44 Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú. Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́.