1 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jésù tún padà wọ Kápánámù, òkìkì kàn pé ó ti wà nínú ilé.
2 Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.
3 Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.
4 Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù.
5 Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,
7 “È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? O ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”