14 Bí ó ti ń rin etí òkun lọ sókè, ó rí Léfì ọmọ Álíféù tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jésù sì wí fún un pé, “Tẹ̀ lé mi,” Léfì dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.
15 Ó si ṣe, bí ó sì ti jókòó tí oúnjẹ ni ilé Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí ti wọn pọ̀ ti wọn tẹ̀lé e.
16 Nígbà tí àwọn olùkọ òfin àti àwọn Farisí rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “È é ti rí tí ó fi ń bá àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
17 Nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá lati sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀?”
19 Jésù dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò se máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó sì wà lọ́dọ̀ wọn?
20 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.