Máàkù 2:18-24 BMY

18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀?”

19 Jésù dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò se máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó sì wà lọ́dọ̀ wọn?

20 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.

21 “Kò si ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ túntún lẹ ògbólógbo ẹ̀wù, bí ó ba se bẹ́ẹ̀, èyí túntún ti a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fà ya kúrò lára ògbólógbòó, yíyọ́ rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.

22 Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì túntún sínú ìgò wáìni ògbólógbó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a si dàànu, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”

23 Ó sì ṣe ni ọjọ ìsinmi, bí Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń kọjá lọ láàrin oko ọkà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya ìpẹ́ ọká.

24 Díẹ̀ nínú àwọn Farisí wí fún Jésù pé, “Wò ó, è é ṣe ti wọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”