24 Díẹ̀ nínú àwọn Farisí wí fún Jésù pé, “Wò ó, è é ṣe ti wọn fi ń ṣe èyí ti kò yẹ ni ọjọ́ ìsinmi.”
25 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yín kò tí kà ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ó ṣe aláìní, tí ebi sì ń pa á, òun àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀?
26 Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Ábíátarì olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ búrẹ́dì ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”
27 Ó sì wí fún wọ́n pé, a dá ọjọ́ ìsinmi fún ènìyàn, “Ṣùgbọ́n a kò dá ènìyàn fún ọjọ ìsinmi.
28 Nítorí náà Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú.”