6 Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,
7 “È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? O ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
8 Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
9 Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, ki o si máa rin?’
10 Ṣùgbọ́n ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Ènìyàn ní agbára ní ayé làti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ní.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé,
11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ẹní rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.”
12 Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé ẹní rẹ̀. Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”