21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wá láti mu un lọ ilé, nítorí tí wọn wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”
22 Àwọn olùkọ́ni-ni-òfin ṣọkàlẹ̀ wá láti Jérúsálẹ́mù, wọn sì wí pé, “Ó ni Béélísébúbù, olórí àwọn ẹ̀mí Èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”
23 Jésù pè wọ́n, ó sì fi òwé bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èsù ṣe lè lé èsù jáde?
24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀.
25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò leè dúró.
26 Bí Èṣù bá sì díde sí ara rẹ, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé.
27 Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní erù lọ, bí kò se pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀.