1 Jésù sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ní létí òkun Àwọn ijọ̀ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí òkun.
2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé:
3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.
4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.
5 Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpátá, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hú jáde.