18 Àwọn tí ó bọ́ sáàrin ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á.
19 Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso.
20 Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbà á lótìítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run, ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùnún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
21 Ó si wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fí sábẹ́ òsùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, kí á máa sì se gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà?
22 Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsinyìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkòkọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba
23 Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ maá kíyèsí ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n náà ni a ó fi wọ̀n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.