23 Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
24 Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ maá kíyèsí ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùnwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ̀n náà ni a ó fi wọ̀n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.
25 Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún síi àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ń, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”
26 Ó sì tún ọ èyí pé, “Èyí ni a lè fí ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀.
27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìdè, irúgbìn náà hù jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀.
28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ni orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó.
29 Nígbà tí èṣo bá gbó tan, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòje bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”