30 Jésù sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀?
31 Ó dàbí èso hóró Músítádì kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan níńu àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbin sínú ilẹ̀.
32 Ṣíbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbà sókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgba yókù lọ. Ó sì ya ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbò-bò.”
33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó.
34 Kìkì òwe ni Jésù fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.
35 Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apákejì.”
36 Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n si gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú-omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀.