38 Jésù ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”
39 Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́ jẹ́ẹ́,” ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà.
40 Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èése tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ ṣíbẹ̀síbẹ̀?”
41 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, tí ìjì àti òkun ń gbọ́ tirẹ̀!”