1 Wọn lọ si apákejì adágún ní ẹba ilẹ̀ àwọn ará Gádárà.
2 Bí Jésù sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀.
3 Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ìbojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é.
4 Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọn ti ń fi ṣẹ́kẹ́sẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹṣẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹṣẹ rẹ. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀.
5 Tọ̀sán-tòru láàrin àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
6 Nígbà tí ó sì rí Jésù látòkèrè, ó sí sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
7 Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ni ṣe tèmi tìrẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀ga Ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.”