15 Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí-èṣù, tí ó jokòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ iye rẹ sì bọ̀ sípọ, ẹ̀rù sì bà wọ́n.
16 Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mí àìmọ́, wọn si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú.
17 Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jésù pé kí ó fi agbégbé àwọn sílẹ̀.
18 Bí Jésù ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú-omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ̀lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ.
19 Jésù kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.”
20 Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapolisi nípa ohun ńlá tí Jésù ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.
21 Nígbà tí Jésù sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí òkun.