21 Nígbà tí Jésù sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí òkun.
22 Ọ̀kan nínú àwọn olórí sínágọ́gù tí à ń pè ni Jáírù wá sọ́dọ̀ Jésù, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
23 Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.”
24 Jésù sì ń bá a lọ.Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
25 Obìnrin kan sì wà láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá.
26 Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i.
27 Nígbà tí ó sì gburo iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.