36 Ṣùgbọ́n bi Jésù ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jáírù pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbà mí gbọ́ nìkan.”
37 Nígbà náà, Jésù dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jáírù, bí kò ṣe Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù.
38 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jésù rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún.
39 Ó wọ inú ilé lọ, Ó sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohunréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.”
40 Wọ́n sì fi í rẹ́rín.Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.
41 Ó gba a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Tàlítà kúùmì” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, díde dúró).
42 Lẹ́sẹ̀kan-náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì ba wọn, ẹnú sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.