36 “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”
37 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Eyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ lébìrà osù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra búrẹ́dì fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”
38 Jésù tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn ún àti ẹja méjì.”
39 Nígbà náà ni Jésù sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹẹgbẹ́ lórí koríko.
40 Lẹ́sẹ̀kan-náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọgọọ́rùn-ún.
41 Nígbà tí ó sì mú ìsù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ ṣíwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn.
42 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó.