10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jésù wọ inú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dálímánútà.
11 Àwọn Farisí tọ Jésù wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ̀n bèèrè fún àmì láti ọ̀run.
12 Jésù mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì? Lóòtọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín?”
13 Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apákejì òkun náà.
14 Sùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú búrédì tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù búrédì kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn.
15 Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó ń mú búrẹ́dì wú àwọn Farisí àti ti Hẹ́rọ́dù.”
16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrin ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú búrédì lọ́wọ́ ni?”