13 Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apákejì òkun náà.
14 Sùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú búrédì tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù búrédì kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn.
15 Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó ń mú búrẹ́dì wú àwọn Farisí àti ti Hẹ́rọ́dù.”
16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrin ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú búrédì lọ́wọ́ ni?”
17 Jésù mọ ohun tí wọ́n sọ láàrin ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èése ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú búrẹ́dì lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsí i sì títí di ìsinyìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni?
18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹyín ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?
19 Nígbà ti mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣà jọ?”Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”