Máàkù 8:22-28 BMY

22 Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.

23 Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí?”

24 Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”

25 Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.

26 Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú.”

27 Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”

28 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”