27 Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”
28 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”
29 Nígbà náà, Jésù bèèrè, “Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́?”Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà.”
30 Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.
31 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le má sàì jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.
32 Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
33 Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”