32 Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
33 Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”
34 Nígbà náà ni Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó ṣe ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.
35 Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là.
36 Nítorí èrè kí ni ó jẹ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù.?
37 Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàsípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?
38 Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panságà àti ẹlẹ́sẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ-Ènìyàn yóò tijú rẹ nígbà tí o bá padà dé nínú ògo Baba rẹ, pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì mímọ́.”