35 Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”
36 Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,
37 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”
38 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”
39 Jésù sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.
40 Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa
41 Lóòótọ́ ni mo sọ fún ún yín bí ẹnikẹ́ni bá fún un yín ní ife omi kan nítorí pé ẹ jẹ́ ti Kírísítì, dájúdájú ẹni náà kì yóò sọ èrè rẹ̀ nù bí ó ti wù kí ó rí.