42 “Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun.
43 Bí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o gbé títí ayé àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ọwọ́ kan ju kí a gbé ọ sínú iná àjóòkú ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì.
44 Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nàá kì í kú
45 Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnú, ó sàn kí ó di agẹ́sẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹṣẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì.
46 Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nàá kì í sì í ku
47 Àti pé, bí ojú rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sí inú iná ọ̀run àpáàdì.
48 Níbi ti“ ‘kòkòrò wọn kìí kú,,tí iná kì í sì í kú.’