21 Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde.
22 Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.”
23 Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.”Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.”
24 Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.”
25 Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli.Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí!
26 Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.”Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.”
27 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.”