Àwọn Ọba Keji 19 BM

Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn Lọ́wọ́ Aisaya

1 Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó bá lọ sinu ilé OLUWA.

2 Ó rán Eliakimu ati Ṣebina ati àwọn àgbààgbà alufaa, tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara wọn, lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya ọmọ Amosi.

3 Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó.

4 Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.”

5 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ ọba fún Aisaya tán,

6 ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á.

7 Ó ní òun óo fi ẹ̀mí kan sinu rẹ̀, tí yóo mú kí ó sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó bá gbọ́ ìròyìn kan, òun óo sì jẹ́ kí wọ́n pa á nígbà tí ó bá dé ilẹ̀ rẹ̀.”

Àwọn Ará Asiria Tún Ranṣẹ Ìhàlẹ̀ Mìíràn

8 Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i.

9 Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé,

10 “Má jẹ́ kí Ọlọrun tí o gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu.

11 O ti gbọ́ ìròyìn ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn tí ó ti bá jagun, pé ó pa wọ́n run patapata ni. Ṣé ìwọ rò pé o lè là?

12 Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n.

13 Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?”

14 Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA.

15 Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.

16 Nisinsinyii, bojú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa; kí o sì gbọ́ bí Senakeribu ti ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ìwọ Ọlọrun alààyè.

17 OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀.

18 Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan.

19 Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.”

Iṣẹ́ Tí Aisaya Rán sí Ọba

20 Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria.

21 Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’

22 Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń kígbe mọ́,tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni!

23 O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

24 Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,mo sì mu omi rẹ̀;ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’

25 “Ṣé o kò mọ̀ péó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni?Èmi ni mo fún ọ ní agbáratí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà.

26 Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára,tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùnbá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé.

27 Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ,mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí.

28 Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.”

29 Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀.

30 Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde.

31 Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é.

32 “Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í.

33 Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

34 N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.”

35 Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́.

36 Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe.

37 Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25