1 Ní ọdún keje tí Jehu jọba ní Israẹli ni Joaṣi jọba ní ilẹ̀ Juda, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ogoji ọdún. Sibaya tí ó wá láti ìlú Beeriṣeba ni ìyá rẹ̀.
2 Ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú OLUWA nítorí pé Jehoiada alufaa ń tọ́ ọ sọ́nà.
3 Ṣugbọn kò ba àwọn pẹpẹ ìrúbọ jẹ́, àwọn eniyan ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń jó turari.
4 Joaṣi pàṣẹ fún àwọn alufaa pé kí wọ́n máa kó àwọn owó ohun mímọ́ tí wọ́n mú wá sí ilé OLUWA pamọ́: ati gbogbo owó tí àwọn eniyan san fún ẹbọ ìgbà gbogbo ati èyí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá.
5 Alufaa kọ̀ọ̀kan ni yóo máa tọ́jú owó tí wọ́n bá mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, yóo sì lo owó náà láti máa tún ilé OLUWA ṣe bí ó ti fẹ́.
6 Àwọn alufaa náà kò tún nǹkankan ṣe ninu ilé OLUWA títí tí ó fi di ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi ti jọba.
7 Nítorí náà, ó pe Jehoiada ati àwọn alufaa yòókù, ó bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi tún ilé OLUWA ṣe? Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ gbọdọ̀ máa kó owó tí ẹ bá gbà sílẹ̀ fún àtúnṣe ilé OLUWA.”
8 Àwọn alufaa náà gba ohun tí ọba sọ, wọ́n sì gbà pé àwọn kò ní máa gba owó lọ́wọ́ àwọn eniyan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní tún ilé OLUWA ṣe fúnra wọn.
9 Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀.
10 Nígbà tí owó bá pọ̀ ninu àpótí náà, akọ̀wé ọba ati olórí Alufaa yóo ka owó náà, wọn yóo sì dì í sinu àpò.
11 Lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn owó náà, wọn yóo gbé àpò owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń kọ́lé;
12 ati fún àwọn ọ̀mọ̀lé, ati àwọn agbẹ́kùúta. Ninu rẹ̀, wọn yóo ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe náà ati láti san owó gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún àtúnṣe ilé OLUWA.
13 Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA,
14 ṣugbọn wọn ń lò ó láti fi san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ ati láti ra àwọn ohun èlò fún àtúnṣe ilé OLUWA.
15 Wọn kò sì bèèrè àkọsílẹ̀ iye tí àwọn tí wọn ń ṣàkóso iṣẹ́ náà ná nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́.
16 Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
17 Ní àkókò náà, Hasaeli, ọba Siria gbógun ti ìlú Gati, ó sì ṣẹgun rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó dojú kọ Jerusalẹmu,
18 Joaṣi, ọba Juda, kó gbogbo àwọn ẹ̀bùn mímọ́ tí Jehoṣafati ati Jehoramu ati Ahasaya, àwọn baba ńlá rẹ̀ tí wọ́n ti jọba ṣáájú rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati èyí tí òun pàápàá ti yà sọ́tọ̀ ati gbogbo wúrà tí ó wà ninu àwọn ilé ìṣúra ilé OLUWA ati èyí tí ó wà ní ààfin, ó fi wọ́n ranṣẹ sí Hasaeli, ọba Siria. Hasaeli bá kó ogun rẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu.
19 Gbogbo nǹkan yòókù tí Joaṣi ọba ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.
20 Àwọn olórí ogun Joaṣi ọba dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ilẹ̀ Milo ní ọ̀nà tí ó lọ sí Sila.
21 Josakari, ọmọ Ṣimeati ati Jehosabadi, ọmọ Ṣomeri, àwọn olórí ogun, ni wọ́n pa á. Wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.