Àwọn Ọba Keji 1 BM

Elija ati Ọba Ahasaya

1 Lẹ́yìn ikú Ahabu ọba, àwọn ará Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli, wọ́n fẹ́ fi tipátipá gba òmìnira.

2 Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn.

3 Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’

4 Ẹ lọ sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘O kò ní sàn ninu àìsàn náà, kíkú ni o óo kú.’ ”Elija sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

5 Àwọn oníṣẹ́ náà pada sọ́dọ̀ ọba, ọba bá bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ fi pada?”

6 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin kan pàdé wa lọ́nà, ó sì sọ fún wa pé, ‘Ẹ pada sọ́dọ̀ ọba tí ó ran yín, kí ẹ sì sọ fún un pé, “OLUWA ní, ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni o fi rán oníṣẹ́ lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi? Nítorí náà o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, o óo kú ni.” ’ ”

7 Ọba bá bèèrè pé, “Irú ọkunrin wo ni ó wá pàdé yín lójú ọ̀nà, tí ó sọ bẹ́ẹ̀ fun yín?”

8 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.”Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.”

9 Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.”

10 Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

11 Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.”

12 Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

13 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí.

14 Iná tí ó wá láti ọ̀run ni ó pa àwọn ọ̀gágun meji ti iṣaaju ati àwọn ọmọ ogun wọn, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́, dá ẹ̀mí mi sí.”

15 Nígbà náà ni angẹli OLUWA sọ fún Elija pé kí ó bá wọn lọ, kí ó má sì bẹ̀rù. Elija bá bá a lọ sọ́dọ̀ ọba.

16 Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.”

17 Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda.

18 Gbogbo nǹkan yòókù tí Ahasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25