Àwọn Ọba Keji 13 BM

Jehoahasi Ọba Israẹli

1 Ní ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi, ọmọ Ahasaya, jọba ní Juda ni Jehoahasi, ọmọ Jehu, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun.

2 Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀.

3 OLUWA bínú sí Israẹli, ó sì jẹ́ kí Hasaeli, ọba Siria, ati Benhadadi ọmọ rẹ̀ ṣẹgun Israẹli ní ọpọlọpọ ìgbà.

4 Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀.

5 (Nítorí náà, OLUWA rán olùgbàlà kan sí Israẹli láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Siria, ọkàn àwọn eniyan Israẹli sì balẹ̀ bíi ti ìgbà àtijọ́.

6 Sibẹsibẹ wọn kò yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti mú Israẹli dá. Wọ́n sì tún ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kan náà, ère oriṣa Aṣera sì wà ní Samaria.)

7 Jehoahasi kò ní àwọn ọmọ ogun mọ́ àfi aadọta ẹlẹ́ṣin, ati kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́wàá ati ẹgbaarun (10,000) àwọn ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn. Ọba Siria ti pa gbogbo wọn run, ó lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi erùpẹ̀.

8 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoahasi ṣe ati agbára rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

9 Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Jehoaṣi Ọba Israẹli

10 Ní ọdún kẹtadinlogoji tí Joaṣi jọba ní Juda ni Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹrindinlogun.

11 Òun náà ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.

12 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya, ọba Juda, jà ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

13 Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ikú Eliṣa

14 Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!”

15 Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn.

16 Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba,

17 ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.”

18 Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró.

19 Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.”

20 Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀.Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli.

21 Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

Ogun Láàrin Israẹli ati Siria

22 Hasaeli ọba Siria kò fi àwọn ọmọ Israẹli lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjọba Jehoahasi.

23 Ṣugbọn OLUWA ṣàánú fún wọn, ó sì yipada sí wọn nítorí majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; kò sì gbàgbé àwọn eniyan rẹ̀.

24 Nígbà tí Hasaeli Ọba kú, Benhadadi ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀.

25 Jehoaṣi ọba, ọmọ Jehoahasi, ṣẹgun Benhadadi ní ìgbà mẹta, ó sì gba àwọn ìlú tí wọ́n ti gbà ní ìgbà ayé Jehoahasi, baba rẹ̀ pada.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25