Àwọn Ọba Keji 3 BM

Ogun láàrin Israẹli ati Moabu

1 Ní ọdún kejidinlogun tí Jehoṣafati jọba ní Juda, Joramu, ọmọ Ahabu, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mejila.

2 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA, ṣugbọn ó wó òpó oriṣa Baali tí Baba rẹ̀ mọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì pọ̀ tó ti baba rẹ̀ tabi ti Jesebẹli ìyá rẹ̀.

3 Ó mú kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bíi Jeroboamu, tí ó ti jọba ṣáájú kò sì ronupiwada.

4 Meṣa, ọba Moabu, a máa sin aguntan; ní ọdọọdún, a máa fún ọba Israẹli ní ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọ̀dọ́ aguntan ati irun ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) àgbò, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀.

5 Ṣugbọn lẹ́yìn tí Ahabu kú, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀, kò san ìṣákọ́lẹ̀ náà fún ọba Israẹli mọ́.

6 Joramu ọba bá gbéra ní Samaria, ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ.

7 Ó ranṣẹ sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ṣé o óo bá mi lọ láti bá a jagun?”Jehoṣafati dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ, ìwọ ni o ni mí, ìwọ ni o sì ni àwọn ọmọ ogun mi ati àwọn ẹṣin mi pẹlu.”

8 Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?”Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.”

9 Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn.

10 Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

11 Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?”Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”

12 Jehoṣafati dáhùn pé, “Wolii òtítọ́ ni.” Àwọn ọba mẹtẹẹta náà bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

13 Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?”Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

14 Eliṣa bá dáhùn pé, “Bí OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn ṣe wà láàyè, n kì bá tí dá ọ lóhùn bí kò bá sí ti Jehoṣafati, ọba Juda, tí ó bá ọ wá.”

15 Ó ní, “Ẹ pe akọrin kan wá.”Bí akọrin náà ti ń kọrin ni agbára OLUWA bà lé Eliṣa,

16 ó bá ní, “OLUWA ní òun óo sọ àwọn odò gbígbẹ wọnyi di adágún omi.

17 Ẹ kò ní rí ìjì tabi òjò, sibẹsibẹ àwọn odò gbígbẹ náà yóo kún fún omi, ti yóo fi jẹ́ pé ẹ̀yin ati àwọn mààlúù yín ati àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóo rí ọpọlọpọ omi mu.

18 Nǹkan kékeré ni èyí jẹ́ níwájú OLUWA, yóo fun yín ní agbára láti borí àwọn ará Moabu.

19 Ẹ óo ṣẹgun àwọn ìlú olódi ati àwọn ìlú dáradára wọn, ẹ óo gé gbogbo igi dáradára, ẹ ó dí gbogbo orísun omi wọn; ẹ óo sì da òkúta sí gbogbo ilẹ̀ oko wọn.”

20 Ní ọjọ́ keji, ní àkókò ìrúbọ òwúrọ̀, omi ya wá láti apá Edomu, títí tí gbogbo ilẹ̀ fi kún fún omi.

21 Nígbà tí àwọn ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba mẹtẹẹta ń bọ̀ láti gbógun tì wọ́n, wọ́n pe gbogbo àwọn tí wọ́n lè lọ sógun jọ, ati àgbà ati ọmọde, wọ́n sì fi wọ́n sí àwọn ààlà ilẹ̀ wọn.

22 Nígbà tí wọ́n jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, tí oòrùn ń ràn sórí omi náà, àwọn ará Moabu rí i pé omi tí ó wà níwájú àwọn pọ́n bí ẹ̀jẹ̀.

23 Wọ́n kígbe pé, “Ẹ wo ẹ̀jẹ̀! Dájúdájú àwọn ọba mẹtẹẹta wọnyi ti bá ara wọn jà, wọ́n sì ti pa ara wọn, ẹ jẹ́ kí á lọ kó ìkógun ninu ibùdó-ogun wọn.”

24 Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ibùdó-ogun náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli kọlù wọ́n, títí tí wọ́n fi sá pada; wọ́n sì ń pa wọ́n ní ìpakúpa bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.

25 Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀.

26 Nígbà tí ọba Moabu rí i pé ogun náà le pupọ, ó mú ẹẹdẹgbẹrin (700) ọkunrin tí wọ́n ń lo idà, ó gbìyànjú láti la ààrin ogun kọjá níwájú ọba Edomu, ṣugbọn kò ṣeéṣe.

27 Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25