Àwọn Ọba Keji 10 BM

A Pa Àwọn Ọmọ Ọba Ahabu

1 Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní:

2 “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ọba, ẹ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ẹṣin, ati àwọn ohun ìjà ati àwọn ìlú olódi ní ìkáwọ́ yín. Nítorí náà, ní kété tí ẹ bá gba ìwé yìí,

3 ẹ fi èyí tí ó bá jẹ́ akọni jùlọ lára àwọn ọmọ ọba sí orí oyè, ẹ sì múra láti jà fún ilẹ̀ oluwa yín.”

4 Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ní, “Ǹjẹ́ àwa lè bá Jehu, ẹni tí ó ṣẹgun ọba meji jà?”

5 Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.”

6 Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.”Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria.

7 Nígbà tí wọ́n rí ìwé Jehu gbà, àwọn olórí Samaria pa gbogbo àwọn ọmọ Ahabu, wọ́n sì kó orí wọn sinu apẹ̀rẹ̀ lọ fún Jehu ní Jesireeli.

8 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún Jehu pé wọ́n ti kó orí àwọn ọmọ Ahabu dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn jọ sí ọ̀nà meji ní ẹnubodè ìlú, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

9 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jehu lọ sí ẹnubodè ìlú, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, “Ẹ kò ní ẹ̀bi, èmi ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí Joramu ọba, oluwa mi, tí mo sì pa á. Ṣugbọn ta ni ó pa àwọn wọnyi?

10 Èyí fihàn dájú pé gbogbo ohun tí OLUWA sọ nípa ìdílé Ahabu yóo ṣẹ. OLUWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí láti ẹnu Elija, wolii rẹ̀.”

11 Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu tí wọn ń gbé Jesireeli ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn alufaa; kò dá ọ̀kan ninu wọn sí.

A Pa Àwọn Ìbátan Ahasaya Ọba

12 Jehu kúrò ní Jesireeli, ó ń lọ sí Samaria. Nígbà tí ó dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Bẹtekedi, níbi tí àwọn olùṣọ́ aguntan ti máa ń rẹ́ irun aguntan,

13 ó pàdé àwọn ìbátan Ahasaya, ọba Juda, ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?”Wọ́n dáhùn pé, “Ìbátan Ahasaya ni wá. Jesireeli ni à ń lọ láti lọ kí àwọn ọmọ ọba ati àwọn ìdílé ọba.”

14 Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí.

A Pa Àwọn Ìbátan Ahabu yòókù

15 Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?”Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

16 Ó ní, “Tẹ̀lé mi, kí o wá wo ìtara mi fún OLUWA.” Wọ́n sì jọ gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Samaria.

17 Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija.

A Pa Àwọn Abọ̀rìṣà Baali

18 Lẹ́yìn náà, Jehu pe gbogbo àwọn ará Samaria jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ahabu sin oriṣa Baali díẹ̀, ṣugbọn n óo sìn ín lọpọlọpọ.

19 Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni.

20 Ó pàṣẹ pé, “Ẹ ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsìn Baali,” wọ́n sì kéde rẹ̀.

21 Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji.

22 Jehu sì pàṣẹ fún ẹni tí ń tọ́jú ibi tí wọn ń kó aṣọ ìsìn pamọ́ sí pé kí ó kó wọn jáde fún àwọn tí ń bọ Baali.

23 Lẹ́yìn èyí, Jehu ati Jehonadabu lọ sinu ilé ìsìn náà, ó ní, “Ẹ rí i dájú pé àwọn olùsìn Baali nìkan ni wọ́n wà níhìn-ín, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń sin OLUWA níbí.”

24 Òun pẹlu Jehonadabu bá wọlé láti rú ẹbọ sísun sí Baali. Ṣugbọn Jehu ti fi ọgọrin ọkunrin yí ilé ìsìn náà po, ó sì ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n wá jọ́sìn níbẹ̀. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí ẹnìkan lọ, pípa ni a óo pa á.

25 Ní kété tí Jehu parí rírú ẹbọ sísun rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ ati àwọn olórí ogun pé kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì pa gbogbo wọn; ẹnikẹ́ni kò si gbọdọ̀ jáde. Wọ́n bá wọlé, wọ́n fi idà pa gbogbo wọn, wọ́n sì wọ́ òkú wọn síta. Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ inú ibi mímọ́ Baali lọ,

26 wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná.

27 Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí.

28 Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli.

29 Ṣugbọn Jehu tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú kí Israẹli bọ ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó wà ní Bẹtẹli ati Dani.

30 OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.”

31 Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé.

Ikú Jehu

32 Ní àkókò náà ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí dín ilẹ̀ Israẹli kù. Hasaeli ọba Siria gba gbogbo àwọn agbègbè Israẹli,

33 láti ìhà ìlà oòrùn Jọdani, gbogbo ilẹ̀ Gileadi ati ti ẹ̀yà Gadi, ẹ̀yà Reubẹni ati ẹya Manase. Láti Aroeri tí ó wà ní àfonífojì Arinoni tíí ṣe ilẹ̀ Gileadi ati ilẹ̀ Baṣani.

34 Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehu ṣe, ati bí ó ti lágbára tó, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

35 Jehu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sí Samaria, Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

36 Gbogbo àkókò tí Jehu fi jọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún mejidinlọgbọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25