9 Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run.
10 Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.”
11 Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi.
12 Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa.
13 Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé.
14 Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?”Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.”
15 Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà.