10 Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé yóo kú, ṣugbọn lọ sọ fún un pé yóo yè.”
11 Eliṣa tẹjú mọ́ Hasaeli títí ojú fi tì í. Eliṣa sì sọkún.
12 Hasaeli bèèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń sunkún, oluwa mi?”Eliṣa dáhùn pé, “Nítorí pé mo mọ oríṣìíríṣìí nǹkan burúkú tí o óo ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli: O óo jó ibi ààbò wọn, o óo fi idà pa àwọn ọmọkunrin wọn, o óo tú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn ká, o óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”
13 Hasaeli dáhùn pé, “Ta ni mí, tí n óo fi ṣe nǹkan tí ó lágbára tóbẹ́ẹ̀?”Eliṣa dáhùn pé, “OLUWA ti fi hàn mí pé o óo jọba ní Siria.”
14 Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Benhadadi, ó sì bèèrè ohun tí Eliṣa sọ lọ́wọ́ rẹ̀.Hasaeli dáhùn pé, “O óo yè ninu àìsàn rẹ.”
15 Ní ọjọ́ keji Hasaeli mú aṣọ tí ó nípọn, ó rì í bọ omi, ó sì fi bo ojú Benhadadi títí ó fi kú.Hasaeli sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
16 Ní ọdún karun-un tí Joramu ọmọ Ahabu jọba ní Israẹli, ni Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní ilẹ̀ Juda.